Ìgbésùnmọ̀mí: Àjọ ECOWAS fẹ́ẹ́ ṣèrànwọ́ fún ilẹ̀ Nàíjíríà

Kayọde Ọmọtọṣọ

Ajọ iṣọkan ọrọ aje ilẹ Adulawọ, iyẹn ECOWAS, ti ṣetan lati dide iranwọ fun orileede Naijiria ati awọn ilẹ Adulawọ mi-in lati gbogun ti iwa igbesunmọmi nilẹ Adulawọ, pẹlu iranwọ ikọ ologun ti ajọ ọhun yoo dasilẹ. Koda, biliọnu meji ataabọ Dọla ni wọn ti ko jọ lati fi ṣe idasilẹ ikọ ologun naa. Kọmisanna ajọ naa to n ri sọrọ to jẹ mọ oṣelu ati eto aabo, Abdel-Fatau Musah, lo sọ eleyii di mimọ niluu Abuja, lanaa.

O ni “ti ẹ ba wo agbegbe wa, iwa igbesunmọmi ti gbilẹ si i. Lonii, orileede Burkinafaso ti n ṣaaju Afghanistan gẹgẹ bi orileede ti iwa igbesunmọmi ti gbilẹ lagbaaye, ti ilẹ Adulawọ si ti di ile fun awọn agbesunmọmi. Iyalẹnu lo jẹ fun wa pe ọkan ninu orileede to jẹ ẹgbẹ wa le maa koju iwa igbesunmọmi. Ti iru eyi ba fi le ṣẹlẹ ni orileede kan, o tumọ si pe awọn orileede yooku ko gbọdọ sun asunpiye. A ti iru itu ti wọn pa ni awọn orileede kan bii Benin, Togo, Ghana ati Cote d’voire.”

   Musah waa ni inu oun dun fun bi ijọba ilẹ Naijiria ṣe ṣẹgun ikọ Boko Haram ti awọn naa fẹẹ sọ ara wọn di kanranjangbọn, ti wọn si sọ ikọ ọhun di ẹdun arinlẹ.

Subscribe to our Newsletter

* indicates required

Intuit Mailchimp